Close sidebar
Skip to content

AKORI EKO: ATUNYEWO APEJUWE IRO KONSONANTI ATI IRO FAWELI

Iro konsonanti ni awon iro ti idiwo maa n wa fun eemi ti a fi n gbe won jade.

Idiwo le waye nipa ki ona eemi se patapata, ki iro jade pelu ariwo taki ki o se die ki iro jade ni irorun. Awon iro konsonanti ede Yoruba ni:

d, b, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ṣ, t, w, y.

ABUDA IRO KONSONANTI: Ti a ba fe se apejuwe iro konsonanti nipa abuda, a nilati wo awon ilana wonyi wo ni okookan:

 • Orison eemi ti a fi n pe iro
 • Irufe eemi ti a lo
 • Ipo alafo tan-an-na
 • Ipo afase
 • Irufe afipe ti a lo
 • Irufe idiwo ti o wa fun eemi

Orisun eemi ti a fi pe iro: A nilati so orison eemi ti a lo lati pe iro konsonanti, yala

 • Eemi edo-foro lati inu edo-foro ni tabi
 • Eemi amisinu ti a seda re wa ni enu

Eemi edo-foro ni a fi n gbe gbogbo konsonanti ayafi iro /kp/ ati /gb/ ti a n lo apapo eemi edo-foro ati eemi ti a seda re wa ni enu.

Irufe eemi ti a fi gbe iro jade: A nilati so iru eemi ti a fi gbe iro konsonanti jade: Yala

 • Eemi amisode;
 • Eemi amisinu; tabi
 • Apapo eemi mejeeji (bi o se ri ti a ba pe iro /kp/ ati /gb/)

Ipo alafo tan-an-na: A nilati so ipo tan-an-na ofun wa boya

 • Ipo imi (fun iro aikunyun) tabi
 • Ipo ikun (fun iro akunyun)

Ipo ti afase wa: A nilati so boya

 • Afase gbera soke di kaa imu ni tabi
 • Afase wale fun eemi lati gba kaa enu ati imu jade leekan naa.
See also  AKOLE ISE: Akoto ode-oni

Irufe afipe ti a lo: A nilati fi han boya

 • Afipe asunsi ni a n lo tabi
 • Afipe akanmole
 • Ipa ti afipe kookan ko nogba ti a ba pe iro konsonanti.

Irufe idiwo to wa fun eemi ti a lo: A gbodo so irufe idiwo ti o sele si eemi ni opona ajemohun, boya

 • Ona se patapata ni; tabi
 • Alafo die si sile fun eemi lati koja

A le wa se apejuwe abuda iro konsonanti ni okookan bayii. Bi apeere: iro /b/:

 • Orison eemi –           eemi edo-foro ni a lo
 • Irufe eemi –           eemi amisode
 • Ipo alafo tan-an-na –           alafo tan-an-na wan i ipo ikun
 • Ipo afase –           afase gbera soke di ona si imu
 • Irufe afipe –           ete isale (asunsi) pade ete oke (akanmole)
 • Iru idiwo –           ona eemi se patapata ni sakani ete mejeeji

ATE KONSONANTI

Ate yii fi gbogbo alaye wa lori owoo konsonanti han ni soki.

Ona Isenupe Afeji-ete-pe Afeyin-fete-pe Aferi-gipe Afaja-fe-rigi-pe Afajape Afafasepe Afitan-an-nape Afafa-sefete-pe
Asenupe Akunyun

Aikunyin

b d

t

g

k

gb

p

Aseesetan Akunyun y w
Asesi Akunyun j
Afunnupe Aikunyun f s h
Afegbe-enu-pe Akunyun l
Aranmupe Akunyun m n
Arehon Akunyun r

DIDARUKO IRO KONSONANTI

A le se apejuwe iro konsonanti bayii:

[b]        Konsonanti akunyun afeji-ete-pe asenupe

[d]        konsonanti akunyun aferigipe asenupe

[g]        Konsonanti akunyun afafasepe asenupe

[gb]      Konsonanti akunyun afafasefetepe asenupe

[f]        Konsoanti aikunyun afeyinfete afunnupe

[h]        Konsonanti aikunyun afitan-an-nape afunnupe

[dz]      Konsonanti akunyun afajaferigipe asesi

[k]        Konsonanti aikunyun afafasepe asenupe

[l]         Konsonanti akunyun aferigipe afegbe-enu-pe

[m]      Konsonanti akunyun afeji-ete-pe aranmu

[n]        Konsonanti akunyun aferigipe aranmu

[kp]      Konsonanti aikunyun afafasefetepe asenupe

[r]        Konsonanti akunyun aferigipe arehon

[s]        Konsonanti aikunyun aferigipe afunnupe

[ʃ]         Konsonanti aikunyun afajaferigipe afunnupe

[t]        Konsonanti aikunyun aferigipe asenupe

[w]       Konsonanti akunyun afafasefetepe aseesetan

[j]         Konsonanti akunyun afajape aseesetan.

 

 

IRO FAWELI: Faweli ni awon iro ti a pe jade nigba ti ko si idiwo Kankan fun eemi to n ti inu edo-foro bo.

Iro faweli ede Yoruba pin si orisii meji. Awon ni:

 • Faweli airanmupe: a, e, ҿ, i, o, ϙ, u
 • Faweli aranmupe: an, ҿn, in, ϙn, un

Lati se apejuwe abuda iro faweli ede Yoruca, a nilati ye ipo ti awon eya ara ifo meta wonyi wa wo:

 • ahon
 • afase, ati
 • ete

Ipo ti ahon wa: A gbodo se akiyesi

 • apa kan ara ahon to gbe soke julo ninu enu (boya iwaju, aarin tabi eyin ahon)
 • bi apa kan to gbe soke naa se ga to ni enu. Bi apeere, bi a ba pe iro /i/:
 • iwaju ahon lo gbe soke jule ni enu
 • giga iwaju ahon feree de oke tente ni enu

ATE FAWELI: Ate isaje yii ni so ipo tabi irisi ahon ni enu ti a ba gbe iro faweli kookan jade.

Faweli airanmupe

 

See also

AKORI EKO: ATUNYEWO AWON EYA ARA IFO

AKORI EKO: ITESIWAJU AWON ORISA ILE YORUBA

AKORI EKO: ITESIWAJU ONKA YORUBA

AKORI EKO: ITESIWAJU EKO LORI ONA IBANISORO

OSE KERIN-IN

SUBSCRIBE BELOW FOR A GIVEAWAY

Building & maintaining an elearning portal is very expensive, that is why you see other elearning websites charge fees. Help to keep this learning portal free by telling mum or dad to donate or support us. Thank you so much. Click here to donate

Leave a Reply

Your email address will not be published.

error: Content is protected !!