ETO ISELU ABINIBI ATI ODE ONI

Ipa ti  baale  ile, Iyaale-ile omobinrin ile, omokunrin ile, omo osu n ko ninu eto       isakoso agbo ile ati ebi gbigboona.

Eto iselu ni ile Yoruba bere lati inu ile, gege bi asa ,baba ni Olori ile, iya ni atele bee ni awon omo naa ni ojuse bi ojo ori won ba se telera.

Eto agbo-ile ni ipile eto ijoba ni ile Yoruba. Olori agbo-ile ni

Baale: ni  eni ti o ba dagba ju lo ni o n je oye yii. Kii se oye ti a maa n du, ti bale kan ba ku ni eni ti o ba tun dagba ju miran yoo je.

Baale ni alase ati alakooso agbo ile, Ohun ti o ba so ni abe ge. Ko si eni ti o gbodo fi owo pa ida re loju.

 

Ile maa n to beere ninu agbo ile nla ni won a wa mo ogiri yii gbogbo ile bee ka,       ilekun kan yoo wa ni enu ona  abawole tabi abajade kuro ninu agbo ile.

Baale kii gbe eyin odi, aarin agbo – ile ni o maa n gbe lati mojuto gbogbo ohun ti o ba n lo.

Igbejo maa n wa ti won maa n jokoo si lati gbo ejo pelu awon agbaagba bii merin. Omo kekere kan yoo maa fe abebe si baba ni ara.

 

ISE Baale

Ija pipari ni agbo-ile: ti  ede aiyede ba waye ise baale ni lati yanju re. Totun tosi yoo ro ejo, ki in to da ejo, bale lo maa kadii ninu ohun to ba si so ni abe ge.

Fifi omo foko: bi omobinrin ile bafe loko, odede bale ni won yoo ti wule fun-un. Bi iyawo tuntun ba si wole o gbodo de odede baale fun adura.

 

Imojuto omo ile lokunrin ati lobinrin o gbodo mo Ijade at iwole awon odo agbo ile.

Ogun pipin: Odede baale ni won ti n saato bi won yoo se pin ogun fun awon omo oku ni idi igi kookan.

Iyaale: ni Obinrin ti o dagba ju ni iye odun ti won wo ile oko. Oun ni igbakeji bale ninu eto iselu agbo ile.

 

O je asoju ati alamojuto awon iyawo ile ati omobinrin ile.

Ise re ni lati mo igba ati akoko ti a bi omo lati yanju aawo ti o waye nipa ojo ori.

Oun ni yoo toju iyawo asesegbe oyun inu, omo ikoko ati eto ila kiko fun omo tuntun.

Iyaale gbodo ni imo kikun nipa ita idile, oriki ile oko, ti yoo si maa ko awon atele re gbogbo.

 

Omokunrin Ile: ni awon gende okunrin ti won ti laya tabi ki won je odo.

Awon ni bale maa n ran ni ise bi ile oku gbigbe, oko ile riro, ona yiye, oju ogun lilo sisin ibi omo si baluwe abbl awon ni won n pa eran nibi inawo apa eran ni won maa n fun won. Won maa n wa nibi ti bale ti n pari ija.

 

Obinrin ile,! Awon ni iyawo agbo-ile, ojuse won ni lati rogba yi iyaale ka, ki won sa pa ofin re mo.

 

Awon ni won maa n dana ounje ni akoko odun tabi ayeye. Awon ni won maa n sun rara nibi inawo idile oko won.

 

Awon lo maa n se itoju iyawo titun ati iyawo ile to ba bimo.  Awon lo maa n jora fun iya omoawon lo maa n gba eyin eran.

 

Omo osu Ile -: ni awon agba obinrin ti won ti losi ile oko, ti won wa pada wa maa gbe ni ile baba won.

Won maa n ni enu ninu oro ebi, awon lo maa n gba aya eran ti won ba pa.

 

Omobinrin ile-: ni awon omobinrin ti ko tii lo si ile oko.  Won maa n kopa ninu oro ile

 

Ojuse won ni lati lo ki iyaawo ile to ba bimo.

 

IGBELEWON

  1. Salaye lori Bqql3, Bqql2, *j0y4 zti {ba
  2. Salaye lori Ijoba Ibile Ijoba Ipinle ati Ijoba Apapo.

 

See also

ISEDA ORO-ORUKO

ORO – AYALO

FONOLOJI EDE YORUBA

ASA ELEGBEJEGBE

SILEBU EDE YORUBA

2 thoughts on “ETO ISELU ABINIBI ATI ODE ONI”

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Get Fully Funded Scholarships

Free Visa, Free Scholarship Abroad

           Click Here to Apply

Acadlly