AKORI EKO: ERE IDARAYA

Ere idaraya ni awon ere t tewe – tagba maa n se lati mu ki ara won jipepe. Bi awon Yoruba se feran ise – sise to bee naa ni won ni akoko fun ere idaraya. Akoko ti ise ba dile tabi awon eniyan ba dari bo lati ibi ise oojo won ni won maa n fi aboo si ibi ere idaraya. Ere idaraya wa fun omode ati agbalagba.

A le pin ere idaraya ti o wopo laarin awon Yoruba si meji. Awon ni:

  • Ere osupa ati
  • Ere ojoojumo
  1. ERE OSUPA: ni awon omode maa n se ti ile bat i n sun i akoko osupa nitori aisi ina monamona ni oye ojoun (atijo)

Awon ere bee ni:

  1. Bojuboju
  2. Ekun meran
  • Eye meloo tolongo waye
  1. Booko – booko
  2. Isa – n – saa – lu – bo
  3. Kini newu
  • Alo apamo ati alo apagbe
  1. ERE OJOOJUMO: eyi ni ere ti tomode – tagba maa n se ni owo osan si irole. Iwonyi le je ere abe ile bii: (i) ayo tita (ii) moni – ni – moni – ni
  2. ERE ITAGBANGBA: eyi le je:

(i) eke tabi ijakadi       (ii) okoto tita   (iii) Ere arin

ANFAANI ERE IDARAYA

  1. O n mu nii ronu jinle
  2. O n je ki a mo nipa oro ati itan atijo (atayebaye)
  • Erin ati awada maa n waye
  1. O maa n ko ni bi a ti ri fi oju sun ohun okere (ninu ere arin)
  2. O n mu ki omode ni agbara ki o si ni aya lati le koju sioro (ija fun idaraya kii je ki omode saisan)
  3. O n mu ajosepo to danmoran wa laarin awon omode
  • O n mu ki omode gbagbe wahala ise oojo.

ALEEBU ERE IDARAYA

  1. O maa n gba akoko eniyan
  2. Oro iwosi maa n waye ninu ere idaraya (ayo tita)
  3. Erupe le gbon si oju omode rabi ki emomiran kan ni orun ese nibi ti won ti n sare kiri
  4. Eniyan le ti ibi ijakadi di alaabo ara titi ojo aye onitohun.

ASA IRANRA – ENI LOWO (COMMUNAL ASSISTANCE)

Asa iranra – eni lowo je ona ti awon Yoruba fi maa n ran ara won lowo ni aye atijo. Asa yii maa n saba jeyo ninu ise oko riro, ile kiko, owo yiya tabi n kan miiran.

Asa iranra – eni lowo maa n mu ki ise ti o po ti o le gba eniyan ni akoko pupo di sise ni kiakia nipa pipapo se e. ilana jijumo se ise papo maa n mu ki okun ife nipon, o si maa n je ki wahala dinku laarin awon eniyan ti won wan i ayka kan naa.

Orisii ona iranra – eni lowo

  1. Owe
  2. Aaro
  • Ajo
  1. Esusu
  2. Owo ele kiko (so ogundogoji)
  3. San – an – die – die
  • Fifi omo/nnkan ini duro
  1. Aaro: awon odokunrin ti won je ore ti oko won si wan i itosi ara won ni won maa n be ara won ni aaro fun ise oko ti o bap o. olukuluku ni yoo si jumo se e ni ojo kan titi ti won yoo fi se kari ara won. Ounje tabi ohun mimu kii se dandan, sugbon ise naa gbodo yipo kari.
  2. Owe: A maa n be owe ni, opo eniyan bi ebi, ore tabi ojulumo ni a le be lowe lati ba ni sise. Won yoo da ojo owe kii sise dandan lati san owe pada, sugbon eni ti o be lowe gbodo pese ohun jije ati mimu.
  3. Esusu: eyi ni ona ti a maa n gba fi owo pamo lati fise n kan gidi ni ojo iwaju. Ko si ere ninu esusu, sugbon enikan n yoo je olori ti yoo dari won ti gbogbo akopa yoo si fenuko lori akoko ti won fe maa ko boya osose ni tabi osoosu.
  4. Ajo: Awon eniyan le maa dawo jo si owo enikan titi di ipari osu tabi akoko ti won ba fi adehun si. Eni ti o n gba ni yo maa se eto pinpin re, yoo si yo die lori owo eni kookan ni ibere owo ti won n da.
  5. Owo ele kiiko tabi sogundogoji: awon eniyan ti o ba koju isoro to le tabi ti o ba wo wahala, ni won maa n ko owo ele lati fi bo asiri ara won. Nigba miiran ele le je ilopo meji owo ti won ya.
  6. San – an – die – die: eniyan le ra oja awin pelu adehun lati maa san – an owo re pada die – die titi yoo fi san gbogbo oeo naa pada.
  7. Fifi omo tabi ohun ini duro: ti eniyan ba nilo owo, won maa n fi omo tabi nkan ini ti o niye lori duro lati ya owo. Igba ti eni naa ba san iru owo bee tan, ni yoo to gba n kan ti o fi duro pada.

 

See also

AKORI EKO: ATUNYEWO AWON EYA GBOLOHUN

AKORI EKO: EWI AKOMOLEDE

AKORI EKO: APOLA INU EDE YORUBA

ASA ISINKU NI ILE YORUBA

FONOLOJI EDE YORUBA

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Get Fully Funded Scholarships

Free Visa, Free Scholarship Abroad

           Click Here to Apply

Acadlly