AKORI EKO: ATUNYEWO LORI SILEBU EDE YORUBA

Ninu oro ‘baba’ ege meji ni a ni: ‘ba-ba’. Ege kookan ni o ni iro faweli ati ami ohun. Ege kookan yii ni a n pe ni silebu.

ABUDA SILEBU

(i)         Silebu le je iro faweli kan tabi iro konsonanti ati faweli. Apeere:

                                    i – ya

                                    ba – ba

                                    ko – bo

                                    e – gbon

(ii)        Iye ibi ti ohun ba ti je yo ninu oro kan ni yoo fi iye silebu ti oro naa ni han. Bi apeere:

Ife        –          Ibi meji ni ohun ti je yo           (Silebu meji)

Omuti –          Ibi meta ni ohun ti je yo          (Silebu meta)

Ikadii   –          Ibi merin ni ohun ti je yo        (Silebu merin)

IHUN SILEBU

Apa meji ni silebu pin si. Awon ni:

  • Odo silebu
  • Apaala silebu

(i)         Odo Silebu: Odo silebu ni ipin ti a maa n gbo ketekete ti a ba pe ege silebu kan. Ori re ni ami ohun n wa. Iro faweli tabi konsonanti aranmu asesilebu ‘n’ ni won le je odo silebu. Odo silebu ni a fala si nidii wonyi:

i-wa

i-gba-la

o-ron-bo

(ii) Apaala Silebu: Awon iro ti a ki i gbo ketekete ti a ba pe oro sita. Konsonanti inu silebu ni o maa n duro bii apaala silebu. Apaala silebu ni a fala si nidii wonyi:

i-wa

o-san

du-n-du

EYA IHUN SILEBU

(i)         Silebu Onifaweli Kan (F): Eyi le je eyo faweli kan soso. Apeere iro faweli bee ni a fala si nidii wonyi:

A ti lo

Mo ri o

Mo ka a

15 Places to WIN $10,000
15 Places to WIN $10,000 Cash

Gbogbo iro faweli wonyi le da duro bii silebu:

a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,

a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,

a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,

(ii)        Silebu Alahunpo Konsonanti ati Faweli (KF). Apeere iru silebu bee ni wonyi:

wa, ba, bϙ, bҿ, ri, ra, mo, kϙ

gbϙn, ran, tan, rin, kun, wϙn

(iii)       Konsonanti aranmupe asesilebu (N). Apeere iru silebu bee niyi:

n lϙ

o-ro-n-bo

i-sa-n-sa

PINPIN ORO SI SILEBU

Awon oro kan wa ti won ni ju silebu kan lo ninu ihun. Awon oro bee ni a pe ni ‘oro olopo silebu’. Apeere:

(i)         Oro Onisilebu Meji

Oro Ipin Ihun Iye silebu
ҿgbon

ifҿ

iku

Bϙla

Ҿ-gbon

i-fҿ

i-ku

Bϙ-la

f-kf

f-kf

f-kf

kf-kf

meji

meji

meji

meji

 

(ii)        Oro Onisilebu Meta

Oro Ipin Ihun Iye silebu
Idoti

Agbado

Ijangbon

Kansu

Gbangba

Banjo

Gende

Gbolahan

I-do-ti

a-gba-do

i-jan=gbon

ka-n-su

gba-n-gba

Ba-n-jo

Ge-n-de

Gbo-la-han

f-kf-kf

f-kf-kf

f-kf-kf

kf-n-kf

kf-n-kf

kf-n-kf

kf-n-kf

kf-kf-kf

meta

meta

meta

meta

meta

meta

meta

meta

 

(iii)       Oro Onisilebu Merin:

Oro Ipin Ihun Iye silebu
Ekunrere

Alangba

Opolopo

Olatunji

Mofiimu

Ankoo

Laaro

e-kun-re-re

a-la-n-gba

o-po-lo-po

O-la-tun-ji

Mo-fi-i-mu

a-n-ko-o

la-a-a-ro

f-kf-kf-kf

f-kf-kf-kf

f-kf-kf-kf

f-kf-kf-kf

kf-kf-f-kf

f-n-kf-f

kf-f-f-kf

merin

merin

merin

merin

merin

merin

merin

 

(iv)       Oro Onisilebu Marun-un

Oro Ipin Ihun Iye silebu
Alaafia

Ogunmodede

Ogedengbe

Alagbalugbu

Agbalajobi

Nigbakuugba

a-la-a-fi-a

o-gun-mo-de-de

o-ge-de-n-gbe

a-la-gba-lu-gbu

a-gba-la-jo-bi

ni-gba-ku-u-gba

f-kf-f-kf-f

f-kf-kf-kf-kf

f-kf-kf-kf-n-kf

f-kf-kf-kf-kf

f-kf-kf-kf-kf

kf-kf-kf-f-kf

marun-un

marun-un

marun-un

marun-un

marun-un

marun-un

 

(v)        Oro Onisilebu Mefa

Oro Ipin Ihun Iye silebu
Gbangbayikita

Orogodoganyin

Afarajoruko

Alapandede

Konsonanti

Bookubooku

Gba-n-gba-yi-ki-ta

o-ro-go-do-gan-yin

a-fa-ra-jo-ru-ko

a-la-pa-n-de-de

ko-n-so-na-n-ti

bo-o-ku-bo-o-ku

kf-n-kf-kf-kf-kf

f-kf-kf-kf-kf-kf

f-kf-kf-kf-kf-kf

a-kf-kf-n-kf-kf

kf-n-kf-kf-f-kf

kf-f-kf-kf-f-kf

mefa

mefa

mefa

mefa

mefa

mefa

 

ISE AMUTILEWA

  1. (a) Ki ni Silebu? (b) So abuda silebu meji ti o mo pelu apeere
  2. Ko apeere oro marun-un ti o ni konsonanti aranmupe asesilebu. Pin won si iye silebu.
  3. Pin awon oro wonyi si iye silebu won:

(i) Akalamagbo           (ii) Olododo                 (iii) Aworerin-in          (iv) Akikanju

(v) Osoosu                   (vi) egbeegberun        (vii) ileladewa             (viii) igbaradi

(ix) iyaloosa                 (x) Akerefinusogbon

 

See also

AKORI EKO: AROKO AJEMO – ISIPAYA

AKORI EKO: MOFIIMU

AKORI EKO: ATUNYEWO AAYAN OGBUFO

AKORI EKO: ORAN DIDA ATI IJIYA TI O TO

AKORI EKO: IYATO TI O WA LARIN ORO APONLE ATI APOLA APONLE

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Get Fully Funded Scholarships

Free Visa, Free Scholarship Abroad

           Click Here to Apply

Acadlly