Akoto ni sipeli tuntun ti awon onimo ede Yoruba fi enu ko le lori ni odun 1974 lati fi maa ko ede Yoruba sile.
Awon ayipada ti o de ba kiko ede Yoruba sile ni wonyi
SIPELI ATIJO | SIPELI TUNTUN | IFIYESI |
Aiya
Aiye Eiye |
Aya
Aye Eye |
A gbodo yo faweli “I”
nitori a ko pe e |
Otta
Oshogbo Ogbomosho Ebute-Meta |
Ota
Osogbo Ogbomoso Ebute-Meta |
Konsonanti meji kii tele ara ninu ihun ede Yoruba |
Olopa
Alanu Lailai Na Papa Miran Yi |
Olopaa
Alaaanu Laelae Naa Paapaa Miiran Yii |
Iye iro faweli ti a ba pe ni ki a ko sile |
On
Enia Okorin Obirin Nkan Onje |
Oun
Eniyan Okunrin Obinrin Nnkan Ounje |
|
Tani
Kini Gegebi Gbagbo Nitoripe Lehina Biotilejepe |
Ta ni
Kin ni Wi pe Gege bi Gba gbo Nitori pe Leyin naa Bi o tile jepe |
A ni lati ya awon oro yii soto |
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: IWA OMOLUABI ATI ANFAANI RE
Omoluabi ni omo ti a bi ti a si ko ti o gba eko rere.
Ile ni a ti n ko eso rode. ise ati iwa omoluabi bere lati inu ile ti a ti bii.
Lara awon iwa omoluabi ni,
- Iwa ikini
- Bibowo ati titeriba fun agba
- Hihuwa pele lawujo
- Ooto sise
- Iwa irele ati suuru
- Iwa igboran
- Sise oyaye
- Iwa iran-ra-eni lowo.
Igbelewon:
- Kin ni akoto?
- Ko sipeli atijo mewaa ki o si ko akoto re gege bii awon onimo se so
- Fun iwa omoluabi loriki
- Ko iwa omoluabi marun-un ki o si salaye
Ise asetilewa: ko sipeli atijo mewaa ki o si salaye awon ayipada ti o de ba okookan won gege bi awon onimo se fi enu ko ni odun 1974
See also
AKOLE ISE: SISE OUNJE AWUJO YORUBA
AKOLE ISE: ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE
EKO LORI IGBADUN TI O WA NINU LITIRESO ALOHUN
Building & maintaining an elearning portal is very expensive, that is why you see other elearning websites charge fees. Help to keep this learning portal free by telling mum or dad to donate or support us. Thank you so much. Click here to donate